al-`Asr (العَصْر)

Yoruba:Mikail by Yoruba:Mikail

Chapter 103 • 3 verses • Meccan

103:1 Allāhu fi àkókò ìrọ̀lẹ́ ayé búra.
103:2 Dájúdájú ènìyàn wà nínú òfò.
103:3 Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ òdodo láààrin ara wọn, tí wọ́n sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ sùúrù láààrin ara wọn.